Kí ni ìdájọ́ ikú? Ìgbà wo ni wọ́n máa ń pa ẹni tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún?

Bolanle Raheem ati Vandi

Oríṣun àwòrán, others

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹsàn-án oṣù Kẹwàá ọdún 2023 ni ilé ẹjọ́ gíga ní ìpínlẹ̀ Eko dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún ọlọ́pàá Dambri Vandi.

Ẹ̀sùn pípa agbẹjọ́rò Bolanle Raheem ní ọjọ́ Kérésìmesì ọdún 2022 ní agbègbè Ajah ni Vandi kojú tí ilé ẹjọ́ sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn náà.

Adájọ́ Ibironke Harrison tó gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ ní kí wọ́n lọ yẹgi fún Vandi títí tí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lọ́rùn rẹ̀.

Ìbéèrè tó gba ẹnu àwọn ènìyàn lẹ́yìn ìdájọ́ náà ni pé ìgbà wo ni ìdájọ́ ilé ẹjọ́ yìí máa wá sí ìmúṣẹ àti pé ṣé yóò ti ẹ̀ wá sí ìmúṣẹ rárá.

Kí ni o túmọ̀ sí tí wọ́n bá dá ẹjọ́ ikú fún ẹni tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn?

Dambri Vandi

Gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé ẹgbẹ́ àwọn agbẹjọ́rò tẹ̀ka ìlú Ilorin, Amòfin Taofiq Olateju ṣe ṣàlàyé, ohun tó túmọ̀ sí ni pé kí wọ́n lọ pa ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n bá kà si lọ́rùn.

Olateju ṣàlàyé pé onírúurú ọ̀nà ni pípa ènìyàn yìí lè gbà wáyé bí ilé ẹjọ́ bá ṣe gbe kalẹ̀.

Ó ní tí ilé ẹjọ́ bá dá ẹjọ́ ikú fún ènìyàn, yóò sọ irú ọ̀nà tí wọn yóò gbà pa onítọ̀hún.

"Ilé ẹjọ́ le dájú ikú fún ènìyàn nípa fífi ẹ̀yìn rẹ̀ ti àgbá tí à ń pè ní 'firing squad' tàbí kí wọ́n ní kí wọ́n yẹgi fún ẹni náà."

Ó ní àwọn kan wà tí ìjọba ti fún àṣẹ láti mú àwọn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ wá sí ìmúṣẹ àti pé àwọn ènìyàn náà ló máa ṣe àmúṣẹ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ yìí.

Ó fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé gómìnà ìpínlẹ̀ tí ẹni tí wọ́n bá dájọ́ ikú bá wà ló ní ẹ̀tọ́ láti tọwọ́bọ ìwé tí wọ́n ń pè ní 'death warrant' lórí ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún kí àwọn agbófinró tó lè pa ẹni náà.

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n fi lè dájọ́ ikú fún ènìyàn?

Amòfin Jiti Ogunye ṣàlàyé pé ẹ̀sùn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìwé òfin Nàìjíríà la kalẹ̀ láti fi dájọ́ ikú fún ọ̀daràn.

Ogunye kà àwọn ẹ̀sùn náà ní

  • Ẹ̀sùn ìpànìyàn
  • Ẹ̀sùn ìdigunjalẹ̀
  • Ẹ̀sùn ìfipágbàjọba

Bákan náà ló ní wọ́n ti ń ṣe àtúnṣe ìwé òfin láti fi ìjínigbé sínú ẹ̀sùn tí wọ́n le pa ènìyàn lórí.

Ó máa ń tó ìgbà wo kí wọ́n tó pa ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Olateju ṣàlàyé pé kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí ilé ẹjọ́ bá dá ẹjọ́ ikú fún ènìyàn ni wọ́n máa buwọ́lu pípa ẹni náà.

"Kìí ṣe wí pé tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún ènìyàn lónìí, wọ́n máa pá lónìí yẹn náà."

Ó ní ẹni tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún ní àǹfàní oṣù mẹ́ta lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ bá dá ẹjọ́ rẹ̀ kí wọ́n tó lè ṣe àmúṣẹ ìdájọ́ náà.

Ó ṣàlàyé pé ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún yìí ní ànfàní láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn láàárín oṣù mẹ́ta yìí.

Ó fi kun pé tí ilé ẹjọ́ gíga bá gbé ìdájọ́ ikú fún ènìyàn, ẹni náà ní ànfàní láti lọ sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn àti ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ìyẹn Supreme court lórí ìdájọ́ náà.

Ó ní gbogbo àwọn àsìkò tí wọ́n fi ń ṣe ẹjọ́ yìí ni wọn kò ní ẹ̀tọ́ láti dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò títí tí ìgbẹ́jọ́ náà máa fi parí.

"Ó tako ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lábẹ́ òfin láti pa ẹni tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún láàárín oṣù mẹ́ta tó ní láti fi pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn."

Ó tẹ̀síwájú pé lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn bá gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ tán, wọ́n tún ní gbèdéke oṣù kan láti tẹ̀síwájú lọ sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ fún ìgbẹ́jọ́ mìíràn.

Ó fi kun ọ̀rọ̀ pé tí ọ̀daràn tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún kò bá pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ bá ti dá ẹjọ́ rẹ̀ tán, ìjọba ní ẹ̀tọ́ láti buwọ́lu ìwé ikú rẹ̀ lẹ́yìn oṣù mẹ́ta.

Ta ló ni ẹ̀mí ẹni tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún?

Dambri Vandi

Olateju ní ẹni tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún ti di ẹrù ìjọba títí tó máa fi jáde láyé.

"Ìjọba ló ni ẹ̀mí ẹni tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún, ìjọba ni yóò sọ ibi tí yóò máa gbé, oúnjẹ tí yóò máa jẹ, aṣọ tí yóò máa wọ̀ ti wà lọ́rùn ìjọba tó máa fi jáde láyé."

Amòfin Jiti Ogubye ní tirẹ̀ kọminú lórí bí àwọn gómìnà kìí ṣe tọwọ́bọ ìwé ikú fún àwọn tí wọ́n ń dájọ́ ikú fún ní òde òní.

Ogunye wòye pé ó tako ìwé òfin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà bí àwọn gómìnà ṣe ń kọ̀ láti buwọ́lu ìwé náà nítorí òfin ló là á kalẹ̀ pé ẹni tó bá pa ènìyàn pé dandan ni kí wọ́n pa òun náà.

Ó ní tí àwọn gómìnà bá wòye pé ó yẹ kí àyípadà wà lórí òfin yìí, ó yẹ kí wọ́n lọ sí ilé aṣòfin fún àyípadà òfin náà dípò títẹ òfin lójú mọ́lẹ̀.

Bákan náà ló fi kun pé orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé ni irú òfin yìí wà.

Ǹjẹ́ ó ṣeéṣe kí àyípadà bá ẹjọ́ ikú tí wọ́n bá dá fún ènìyàn?

Amòfin Olateju ní ó ṣeéṣe kí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tàbí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yẹ ìdájọ́ ikú fún ẹni tí wọ́n bá dá ẹjọ́ ikú fún tẹ́lẹ̀ ní ilé ẹjọ́ gíga.

Ó ní èyí máa ń wáyé tí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tàbí Supreme Court bá ṣe àtúngbéyẹ̀wò ẹjọ́ náà tí wọ́n sì rí pé ìdájọ́ náà kò bá ẹjọ́ tàbí ẹ̀sùn náà mu.

Bákan náà ló ṣàlàyé pé àwọn ẹ̀rí mìíràn tún lè ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹni tí wọ́n dá ẹjọ́ náà fún kò ṣẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá ẹjọ́ rẹ̀ lé.

Amòfin Ogunye ní àwọn ìgbìmọ̀ kan wà tí wọ́n máa ń dìde láti mú àyípadà bá ìdájọ́ ikú láti fi bèèrè fún ẹ̀wọ̀n àgbéré fún ẹni tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún.